Jónà 2:7-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

7. “Nígbà tí ó rẹ ọkàn mi nínú mi,èmi rántí rẹ, Olúwa,àdúrà mi sì wá sí ọ̀dọ̀ rẹ,nínú tẹ́ḿpìlì mímọ́ rẹ.

8. “Àwọn tí ń fàmọ́ òrìṣà èkékọ àánú ara wọn sílẹ̀.

9. Ṣùgbọ́n èmi yóò fi orin ọpẹ́, rúbọ sí ọ.Èmi yóò san ẹ̀jẹ́ tí mo ti jẹ́.‘Igbàlà wá láti ọdọ Olúwa.’ ”

10. Olúwa sì pàṣẹ fún ẹja náà, ó sì pọ Jónà sí orí ilẹ̀ gbígbẹ.

Jónà 2