28. Lẹ́yìn náà Jésù wí fún wọn pé, “Nígbà tí ẹ mọ̀ pé, nígbà tí ẹ bá gbé Ọmọ ènìyàn sókè, nígbà náà ni ẹ ó mọ̀ pé ẹ̀mi ni àti pé èmi kò dá ohunkóhun ṣe fún ara mi; ṣùgbọ́n bí Baba ti kọ́ mi, èmí ń sọ nǹkan wọ̀nyí.
29. Ẹni tí ó rán mí sì ń bẹ pẹ̀lú mi: kò fi mí sílẹ̀ ní èmi nìkan; nítorí tí èmi ń se ohun tí ó wù ú nígbà gbogbo.”
30. Bí ó ti ń sọ nǹkan wọ̀nyí, ọ̀pọ̀ ènìyàn gbà á gbọ́.
31. Nítorí náà Jésù wí fún áwọn Júù tí ó gbà á gbọ́, pé, “Bí ẹ bá tẹ̀ṣíwájú nínú ọ̀rọ̀ mi ẹ ó jẹ́ ọmọ ẹ̀yin mi nítòótọ́.
32. Ẹ ó sì mọ òtítọ́, òtítọ́ yóò sì sọ yín di òmìnira.”
33. Wọ́n dá a lóhùn pé, “Irú-Ọmọ Ábúráhámù ni àwa jẹ́, àwa kò sì ṣe ẹrú fún ẹnikẹ́ni rí láé; ìwọ ha ṣe wí pé, ‘Ẹ ó di òmìnira’?”
34. Jésù dá wọn lóhùn pé, “Lóòótọ́, lóòótọ́ ni mo wí fún yín, Ẹnikẹ́ni tí ó bá ń dẹ́ṣẹ̀, ẹrú ẹ̀ṣẹ̀ ni.
35. Ẹrú kì í sìí gbé ilé títí láé: ọmọ ní ń gbé ilé títí láé
36. Nítorí náà, bí Ọmọ bá sọ yín di òmìnira ẹ ó di òmìnira nítòótọ́.
37. Mo mọ̀ pé irú-ọmọ Ábúráhámù ni ẹ̀yin jẹ́; ṣùgbọ́n ẹ ń wá ọ̀nà láti pa mí nítorí ọ̀rọ̀ mi kò rí àyè nínú yín. Jésù sọ ọ̀rọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa ara rẹ̀
38. Ohun tí èmi ti rí lọ́dọ̀ Baba ni mo sọ: ẹ̀yin pẹ̀lú sì ń ṣe èyí tí ẹ̀yin ti gbọ́ láti ọ̀dọ̀ baba yín.”