Jòhánù 7:40-44 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

40. Nítorí náà nígbà tí ọ̀pọ̀ nínú ìjọ ènìyàn gbọ́ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, wọ́n wí pé, “Lóòótọ́ èyí ni wòlíì náà.”

41. Àwọn mìíràn wí pé, “Èyí ni Kírísítì náà.”Ṣùgbọ́n àwọn kan wí pé kínla, “Kírísítì yóò ha ti Gálílì wá bí?

42. Ìwé-mímọ́ kò ha wí pé, Kírísítì yóò ti inú irú ọmọ Dáfídì wá, àti Bẹ́tílẹ́hẹ́mù, ìlú tí Dáfídì ti wá?”

43. Bẹ́ẹ̀ ni ìyapa wà láàárin ìjọ ènìyàn nítorí rẹ̀.

44. Àwọn mìíràn nínú wọn sì fẹ́ láti mú un; ṣùgbọ́n kò sí ẹnìkan tí ó gbé ọwọ́ lé e.

Jòhánù 7