Jòhánù 7:31-34 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

31. Ọ̀pọ̀ nínú ìjọ ènìyàn sì gbàágbọ́, wọ́n sì wí pé, “Nígbà tí Kírísítì náà bá dé, yóò ha ṣe iṣẹ́ àmì jù wọ̀nyí, tí ọkùnrin yìí ti ṣe lọ?”

32. Àwọn Farisí gbọ́ pé, ìjọ ènìyàn ń sọ nǹkan wọ̀nyí lábẹ́lẹ̀ nípa rẹ̀; àwọn Farisí àti àwọn olórí àlùfáà sì rán àwọn onísẹ́ lọ láti mú un.

33. Nítorí náà Jésù wí fún wọn pé, “Níwọ̀n ìgbà díẹ̀ ni èmi yóò wà pẹ̀lú yín, èmi yóò lọ sí ọ̀dọ̀ ẹni tí ó rán mi.

34. Ẹ̀yin yóò wá mi, ẹ̀yin kì yóò sì rí mi: àti ibi tí èmi bá wà, ẹ̀yin kì yóò le wà.”

Jòhánù 7