Jòhánù 6:5-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

5. Ǹjẹ́ bí Jésù ti gbé ojú rẹ̀ sókè, tí ó sì rí ọ̀pọ̀ ènìyàn wá sọ́dọ̀ rẹ̀, ó wí fún Fílípì pé, “Níbo ni a ó ti ra àkàrà, kí àwọn wọ̀nyí lè jẹ?”

6. Ó sì sọ èyí láti dán an wò; nítorí tí òun fúnra rẹ̀ mọ ohun tí òun ó ṣe.

7. Fílípì dá a lóhùn pé, “Àkàrà igba owó idẹ kò lè tó fún wọn, bí olúkúlùkù wọn kò tilẹ̀ níí rí ju díẹ̀ bù jẹ.”

8. Ọ̀kan nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, Ańdérù, arákùnrin Símónì Pétérù wí fún un pé,

Jòhánù 6