Jòhánù 6:17-25 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

17. Wọ́n sì bọ́ sínú ọkọ̀ ojú omi, wọ́n sì rékọjá òkun lọ sí Kápénámù. Ilẹ̀ sì ti ṣú, Jésù kò sì tí ì dé ọ̀dọ̀ wọn.

18. Òkun sì ń ru nítorí ẹ̀fúfù líle tí ńfẹ́.

19. Nígbà tí wọ́n wa ọkọ̀ ojú omi tó bí ìwọ̀n ibùsọ̀ mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n tàbí ọgbọ̀n, wọ́n rí Jésù ń rìn lórí òkun, ó sì súnmọ́ ọkọ̀ ojú omi náà; ẹ̀rù sì bà wọ́n.

20. Ṣùgbọ́n ó wí fún wọn pé, “Èmi ni; ẹ má bẹ̀rù.”

21. Nítorí náà wọ́n fi ayọ̀ gbà á sínú ọkọ̀; lójúkannáà ọkọ̀ náà sì dé ilẹ̀ ibi tí wọ́n gbé ń lọ.

22. Ní ijọ́ kéjì nígbà tí àwọn ènìyàn tí ó dúró ní apákejì òkun ríi pé, kò sí ọkọ̀ ojú omi mìíràn níbẹ̀, bí kò ṣe ọ̀kan náà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wọ̀, àti pé Jésù kò bá àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wọ inú ọkọ̀ ojú omi náà, ṣùgbọ́n àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ nìkan ni ó lọ.

23. Ṣùgbọ́n àwọn ọkọ̀ ojú omi mìíràn ti Tiberíà wá, létí ibi tí wọn gbé jẹ àkàrà, lẹ́yìn ìgbà tí Olúwa ti dúpẹ́;

24. Nítorí náà nígbà tí àwọn ènìyàn rí i pé Jésù tàbí ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ kò sí níbẹ̀, àwọn pẹ̀lú wọ ọkọ̀ ojú omi lọ sí Kápánámù, wọ́n ń wá Jésù.

25. Nígbà tí wọ́n sì rí i ní apákejì òkun, wọ́n wí fún un pé, “Rábì, nígbà wo ni ìwọ wá síhín yìí?”

Jòhánù 6