Jòhánù 5:31-35 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

31. “Bí èmi bá ń jẹ́rìí ara mi, ẹ̀rí mi kì í ṣe òtítọ́.

32. Ẹlòmíràn ni ẹni tí ń jẹ́rìí mi; èmi sì mọ̀ pé, òtítọ́ ni ẹrí mi tí ó jẹ́.

33. “Ẹ̀yin ti ránsẹ́ lọ sọ́dọ̀ Jòhánù, òun sì ti jẹ́rìí sí òtítọ́.

34. Ṣùgbọ́n èmi kò gba jẹ̀rìí lọ́dọ̀ ènìyàn: nǹkan wọ̀nyí ni èmi ń sọ, kí ẹ̀yin lè là.

35. Òun ni fìtílà tí ó ń jó, tí ó sì ń tànmọ́lẹ̀: ẹ̀yin sì fẹ́ fún sáà kan láti máa yọ̀ nínú ìmọ́lẹ̀ rẹ̀.

Jòhánù 5