3. Nígbà tí Olúwa mọ nípa èyí, Ó fi Jùdéà sílẹ̀, ó sì tún lọ sí Gálílì lẹ́ẹ̀kan si.
4. Òun sì ní láti kọjá láàárin Samaríà.
5. Nígbà náà ni ó dé ìlú Samaríà kan, tí a ń pè ní Síkárì, tí ó súnmọ́ etí ilẹ̀ oko tí Jákọ́bù ti fi fún Jóṣéfù, ọmọ rẹ̀.
6. Kànga Jákọ́bù sì wà níbẹ̀. Nítorí pé ó rẹ Jésù nítorí ìrìn rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ó jòkó létí kànga: ó sì jẹ́ ìwọ̀n wákàtí kẹfà ọjọ́.
7. Obìrin kan, ará Samaríà sì wá láti fà omi: Jésù wí fún un pé fún mi mu.
8. (Nítorí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ti lọ sí ìlú láti lọ ra ońjẹ.)