29. “Ẹ wá wò ọkùnrin kan, ẹni tí ó sọ ohun gbogbo tí mo ti ṣe rí fún mi: èyí ha lè jẹ́ Krísítì náà?”
30. Nígbà náà ni wọ́n ti ìlú jáde, wọ́n sì tọ̀ ọ́ wá.
31. Láàárin èyí, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ń rọ̀ ọ́ wí pé, “Olùkọ́, jẹun.”
32. Ṣùgbọ́n ó wí fún wọn pé, “Èmi ní ońjẹ láti jẹ, tí ẹ̀yin kò mọ̀.”
33. Nítorí náà ni àwọn ọmọ-èyìn rẹ̀ ń bi ara wọn lérè wí pé, “Ẹnì kan mú ońjẹ fún un wá láti jẹ bí?”
34. Jésù wí fún wọn pé, “Ońjẹ mi ni láti ṣe ìfẹ́ ẹni tí ó rán mi, àti láti parí iṣẹ́ rẹ̀.