Jòhánù 4:23-25 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

23. Ṣùgbọ́n àkókò ń bọ̀, ó sì dé tán nísinsìn yìí, nígbà tí àwọn olùsìn tòótọ́ yóò máa sin Baba ní ẹ̀mí àti ní òtítọ́: nítorí irú wọn ni Baba ń wá kí ó máa sin òun.

24. Ẹ̀mí ni Ọlọ́run: àwọn ẹni tí ń sìn ín kò lè ṣe aláìsìn ín ní ẹ̀mí àti ní òtítọ́.”

25. Obìnrin náà wí fún un pé, mo mọ̀ pé, “Mèsáyà ń bọ̀ wá, tí a ń pè ní Krísítì: Nígbà tí Òun bá dé, yóò sọ ohun gbogbo fún wa.”

Jòhánù 4