13. Wọ́n sì wí fún un pé, “Obìnrin yìí, èé ṣe tí ìwọ fi ń sọkún?”Ó sì wí fún wọn pé, “Nítorí tí wọ́n ti gbé Olúwa mi, èmi kò sì mọ ibi tí wọ́n gbé tẹ́ ẹ sí.”
14. Nígbà tí ó sì ti wí èyí tan, ó yípadà, ó sì rí Jésù dúró, kò sì mọ̀ pé Jésù ni.
15. Jésù wí fún un pé, “Obìnrin yìí, èé ṣe tí ìwọ fi ń sọkún? Ta ni ìwọ ń wá?”Òun ṣebí olùsọ́gbà ní í ṣe, ó wí fún un pé, “Alàgbà, bí ìwọ bá ti gbé e kúrò níhìn yìí, sọ ibi tí o tẹ́ ẹ sí fún mi, èmi ó sì gbé e kúrò.”
16. Jésù wí fún un pé, “Màríà!”Ó sì yípadà, ó wí fún un pé, “Rábónì!” (èyí tí ó jẹ́ Olùkọ́)
17. Jésù wí fún un pé, “Má ṣe fi ọwọ́ kàn mí; nítorí tí èmi kò tíì gókè lọ sọ́dọ̀ Baba mi: ṣùgbọ́n, lọ sọ́dọ̀ àwọn arákùnrin mi, sì wí fún wọn pé, ‘Èmi ń gòkè lọ sọ́dọ̀ Baba mi, àti Baba yín: àti sọ́dọ̀ Ọlọ́run mi, àti Ọlọ́run yín.’ ”
18. Màríà Magídalénè wá, ó sì sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, “Òun ti rí Olúwa!” Àti pé, ó sì ti fi nǹkan wọ̀nyí fún òun.