Jòhánù 19:9-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

9. Ó sì tún wọ inú gbọ̀ngàn ìdájọ́ lọ, ó sì wí fún Jésù pé, “Níbo ni ìwọ ti wá?” Ṣùgbọ́n Jésù kò dá a lóhùn.

10. Nítorí náà, Pílátù wí fún un pé, “Èmi ni ìwọ kò fọhùn sí? Ìwọ kò mọ̀ pé, èmi ní agbára láti dá ọ sílẹ̀, èmi sì ní agbára láti kàn ọ́ mọ́ àgbélébùú?”

11. Jésù dá a lóhùn pé, “Ìwọ kì bá tí ní agbára kan lórí mi, bí kò se pé a fi í fún ọ láti òkè wá: nítorí náà ẹni tí ó fi mí lé ọ lọ́wọ́ ni ó ní ẹ̀ṣẹ̀ pọ̀ jù.”

12. Nítorí èyí Pílátù ń wá ọ̀nà láti dá a sílẹ̀: ṣùgbọ́n àwọn Júù kígbe, wí pé, “Bí ìwọ bá dá ọkùnrin yìí sílẹ̀, ìwọ kì í se ọ̀rẹ́ Késárì: ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe ara rẹ̀ ní ọba, ó sọ̀rọ̀ òdì sí Késárì.”

13. Nítorí náà nígbà tí Pílátù gbọ́ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, ó mú Jésù jáde wá, ó sì jókòó lórí ìtẹ́ ìdájọ́ ní ibi tí a ń pè ní Òkúta-títẹ́, ṣùgbọ́n ní èdè Hébérù, Gábátà.

Jòhánù 19