Jòhánù 19:34-42 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

34. Ṣùgbọ́n ọ̀kan nínú àwọn ọmọ ogun náà fi ọ̀kọ̀ gún un lẹ́gbẹ̀ẹ́, lójú kan náà, ẹ̀jẹ̀ àti omi sì tú jáde.

35. Ẹni tí ó rí sì jẹ́rìí, òtítọ́ sì ni ẹ̀rí rẹ̀: ó sì mọ̀ pé òótọ́ ni òun sọ, kí ẹ̀yin baà lè gbàgbọ́.

36. Nǹkan wọ̀nyí ṣe, kí ìwé mímọ́ ba à lè ṣẹ, tí ó wí pé, “A kì yóò fọ́ egungun rẹ̀.”

37. Ìwé mímọ́ mìíràn pẹ̀lú sì wí pé, “Wọn ó máa wo ẹni tí a gún lọ́kọ̀.”

38. Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí ní Jóṣéfù ará Arimatíyà, ẹni tí ó jẹ́ ọmọ-ẹ̀yìn Jésù, ṣùgbọ́n ní ìkọ̀kọ̀, nítorí ìbẹ̀rù àwọn Júù, o bẹ Pílátù kí òun lè gbé òkú Jésù kúrò: Pílátù sì fún un ní àṣẹ. Nígbà náà ni ó wá, ó sì gbé òkú Jésù lọ.

39. Níkodémù pẹ̀lú sì wá, ẹni tí ó tọ Jésù wá lóru lákọ́kọ́, ó sì mú àdàpọ̀ òjíá àti álóè wá, ó tó ìwọ̀n ọgọ́rún lítà.

40. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n gbé òkú Jésù, wọ́n sì fi aṣọ ọ̀gbọ̀ dì í pẹ̀lú tùràrí, gẹ́gẹ́ bí ìṣe àwọn Júù ti rí ní ìsìnkú wọn.

41. Àgbàlá kan sì wà níbi tí a gbé kàn án mọ́ àgbélébùú; ibojì titun kan sì wà nínú àgbàlá náà, nínú èyí tí a kò tíì tẹ́ ẹnìkan sí rí.

42. Ǹjẹ́ níbẹ̀ ni wọ́n sì tẹ́ Jésù sí, nítorí ìpalẹ̀mọ́ àwọn Júù; nítorí ibojì náà wà nítòòsí.

Jòhánù 19