Jòhánù 18:11-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

11. Nítorí náà Jésù wí fún Pétérù pé, “Tẹ idà rẹ bọ inú àkọ̀ rẹ: ago tí baba ti fi fún mi, èmi ó ṣe aláìmu ún bí?”

12. Nígbà náà ni ẹgbẹ́ ọmọ-ogun àti olórí ẹ̀sọ́, àti àwọn oníṣẹ́ àwọn Júù mú Jésù, wọ́n sì dè é.

13. Wọ́n kọ́kọ́ fà á lọ sọ́dọ̀ Ánnà; nítorí òun ni àna Káyáfà, ẹni tí í ṣe olórí àlùfáà ní ọdún náà.

Jòhánù 18