Jòhánù 16:1-3 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. “Nǹkan wọ̀nyí ni mo ti sọ fún yín, kí a má baà mú yín kọsẹ̀.

2. Wọ́n ó yọ yín kúrò nínú Sínágógù: àní, àkókò ń bọ̀, tí ẹnikẹ́ni tí ó bá pa yín, yóò rò pé òun ń ṣe ìsìn fún Ọlọ́run.

3. Nǹkan wọ̀nyí ni wọ́n ó sì ṣe, nítorí tí wọn kò mọ Baba, wọn kò sì mọ̀ mí.

Jòhánù 16