Jòhánù 15:26-27 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)
26. “Ṣùgbọ́n nígbà tí Olùtùnú náà bá dé, ẹni tí èmi ó rán sí yín láti ọ̀dọ̀ Baba wá, àní Ẹ̀mí òtítọ́ nì, tí ń ti ọ̀dọ̀ Baba wá, òun náà ni yóò jẹ́rìí mi:
27. Ẹ̀yin pẹ̀lú yóò sì jẹ́rí mi, nítorí tí ẹ̀yin ti wà pẹ̀lú mi láti ìpìlẹ̀ṣẹ̀ wá.