Jòhánù 13:9-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

9. Símónì Pétérù wí fún ún pé, “Olúwa, kì í ṣe ẹṣẹ̀ mi nìkan, ṣùgbọ́n àti ọwọ́ àti orí mi pẹ̀lú.”

10. Jésù wí fún un pé, “Ẹni tí a wẹ̀ kò tún fẹ́ ju kí a san ẹṣẹ̀ rẹ̀, ṣùgbọ́n ó mọ́ níbi gbogbo: ẹ̀yin sì mọ́, ṣùgbọ́n kì í ṣe gbogbo yín.”

11. Nítorí tí ó mọ ẹni tí yóò fi òun hàn; nítorí náà ni ó se wí pé, Kìí ṣe gbogbo yín ni ó mọ́

12. Nítorí náà lẹ́yìn tí ó wẹ ẹṣẹ̀ wọn tán, tí ó sì ti mú agbádá rẹ̀, tí ó tún jókòó, ó wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin mọ ohun tí mo ṣe sí yín bí?

13. Ẹ̀yin ń pè mí ní ‘Olùkọ́’ àti ‘Olúwa’: ẹ̀yin wí rere; bẹ́ẹ̀ ni mo jẹ́.

Jòhánù 13