26. Nítorí náà Jésù dáhùn pé, “Òun náà ni, ẹni tí mo bá fi àkàrà fún nígbà tí mo bá fi run àwo.” Nígbà tí ó sì fi run ún tan, ó fi fún Júdásì Ísíkárótù ọmọ Símónì.
27. Ní kété tí Júdásì gba àkàrà náà ni Sátanì wọ inú rẹ̀ lọ.Nítorí náà Jésù wí fún un pé, “Ohun tí ìwọ ń se nì, yára ṣe é kánkán.”
28. Kò sì sí ẹnìkan níbi tábìlì tí ó mọ ìdí tí ó ṣe sọ èyí fún un.
29. Nítorí àwọn mìíràn nínú wọn rò pé, nitorí Júdásì ni ó ni àpò, ni Jésù fi wí fún un pé, Ra nǹkan wọ̀n-ọn-nì tí a kò le ṣe aláìní fún àjọ náà; tàbí kí ó lè fi nǹkan fún àwọn talákà.
30. Nígbà tí ó sì ti gbà òkèlè náà tan, ó jáde lójúkan náà: òru sì ni.
31. Nítorí náà nígbà tí ó jáde lọ tan, Jésù wí pé, “Nísinsìn yìí ni a yin ọmọ-ènìyàn lógo, a sì yin Ọlọ́run lógo nínú rẹ̀.
32. Bí a bá yin Ọlọ́run lógo nínú rẹ̀, Ọlọ́run yóò sì yìn ín lógo nínú òun tìkára rẹ̀, yóò sì yìn ín lógo nísinsìn yìí.
33. “Ẹ̀yin ọmọ mi, nígbà díẹ̀ sí i ni èmi wà pẹ̀lú yín. Ẹ̀yin ó wá mi: àti gẹ́gẹ́ bí mo ti wí fún àwọn Júù pé, Níbití èmi gbé ń lọ, ẹ̀yin kì ó le wà; bẹ́ẹ̀ ni mo sì wí fún yín nísìnsìn yìí.