1. Ara ọkùnrin kan sì ṣe aláìdá, Lásárù, ará Bẹ́tẹ́nì, tí í ṣe ìlú Màríà àti Màta arábìnrin rẹ̀.
2. (Màríà náà ni ẹni tí ó fi òróró ìkunra kun Olúwa, tí ó sì fi irun orí rẹ̀ nù ún, arákùnrin rẹ̀ ni Lásárù í ṣe, ara ẹni tí kò dá.)
3. Nítorí náà, àwọn arákùnrin rẹ̀ ránsẹ́ sí i, wí pé, “Olúwa, wò ó, ara ẹni tí ìwọ fẹ́ràn kò dá.”