Jòhánù 1:35-42 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

35. Ní ọjọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, Jòhánù dúró, pẹ̀lú méjì nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀.

36. Nígbà tí ó sì rí Jésù bí ó ti ń kọjá lọ, ó wí pé, “Wò ó Ọ̀dọ́-àgùntàn Ọlọ́run!”

37. Nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn méjì náà sì gbọ́ ohun tí ó wí yìí, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sì í tọ Jésù lẹ́yìn.

38. Nígbà náà ni Jésù yípadà, ó rí i pé wọ́n ń tọ Òun lẹ́yìn, ó sì béèrè pé, “Kí ni ẹ̀yin ń wá?”Wọ́n wí fún un pé, “Rábì” (ìtumọ̀ èyí tí í ṣe Olùkọ́ni), “Níbo ni ìwọ ń gbé?”

39. Ó wí fún wọn pé, “Ẹ wá wò ó, ẹ̀yin yóò sì rí i.”Wọ́n sì wá, wọ́n sì rí ibi tí ó ń gbé, wọ́n sì wà ní ọ̀dọ̀ rẹ̀ ní gbogbo ọjọ́ náà. Ó jẹ́ ìwọ̀n wákàtí kẹwàá ọjọ́.

40. Ańdérù, arákùnrin Símónì Pétérù, jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn méjì tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ Jòhánù, tí ó sì tọ Jésù lẹ́yìn.

41. Ohun àkọ́kọ́ tí Ańdérù ṣe ni láti wá Símónì arákùnrin rẹ̀, ó sì wí fún un pé, “Àwa ti rí Mèṣáyà” (ẹni tí ṣe Kírísítì).

42. Ó sì mú un wá sọ́dọ̀ Jésù.Jésù sì wò ó, ó wí pé, “Ìwọ ni Símónì ọmọ Jónà: Kéfà ni a ó sì máa pè ọ” (ìtumọ̀ èyí tí ṣe Pétérù).

Jòhánù 1