Jòhánù 1:15-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

15. Jòhánù sì jẹ́rìí nípa rẹ̀, ó kígbe, ó sì wí pé, “Èyí ni ẹni tí mo sọ̀rọ̀ rẹ̀ pé, ‘Ẹni tí ń bọ̀ lẹ́yìn mi pọ̀ jù mí lọ, nítorí òun ti wà ṣáájú mi.’ ”

16. Nítorí láti inú ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀ ni gbogbo wa sì ti gba ìbùkún kún ìbùkún.

17. Nítorí pé nípaṣẹ̀ Mósè ni a ti fi òfin fún ni; oore-ọ̀fẹ́ àti òtítọ́ ti ipaṣẹ̀ Jésù Kírísítì wá.

Jòhánù 1