Jóẹ́lì 2:29-32 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

29. Àti pẹ̀lú sí ara àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ ọkùnrin,àti sí ara àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ obìnrin,ní èmi yóò tú ẹ̀mi mí jáde ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì.

30. Èmi yóò sì fi iṣẹ́ ìyanu hàn ní ọrunàti ní àyé,ẹ̀jẹ̀ àti iná, àti ọ̀wọ́n èéfín.

31. A á sọ oòrùn di òkùnkùn,àti òṣùpá di ẹ̀jẹ̀,kí ọjọ́ ńlá àti ọjọ́ ẹ̀ru Olúwa tó dé.

32. Yóò sí ṣe ẹnikẹ́ni tí ó ba ké pèorúkọ Olúwa ní a ó gbàlà:nítorí ní òkè Ṣíónì àti ní Jérúsálẹ́mùní ìgbàlà yóò gbé wà,bí Olúwa ti wí,àti nínú àwọnìyókù tí Olúwa yóò pè.

Jóẹ́lì 2