Jeremáyà 7:11-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

11. Ṣé ilé yìí, tí a fi orúkọ mi pè ti di ihò àwọn ọlọ́sà lọ́dọ̀ yín ni? Èmi ti ń wò ó! ni Olúwa wí.

12. “ ‘Ẹ lọ nísinsìn yìí sí ṣílò níbi ti mo kọ́ fi ṣe ibùgbé fún orúkọ mi, kí ẹ sì rí ohun tí mo ṣe sí i nítorí ìwà búburú Ísírẹ́lì tí í ṣe ènìyàn mi.

13. Nígbà tí ẹ̀yin ń ṣe àwọn nǹkan wọ̀nyí ni èmi bá a yín sọ̀rọ̀ léraléra ni Olúwa wí ẹ̀yin kò gbọ́, èmi pè yín, ẹ̀yin kò dáhùn

Jeremáyà 7