Jeremáyà 50:5-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

5. Wọn ó máa bèèrè ọ̀nà Síhónì, oju wọnyóò sì yí síhà ibẹ̀, wí pé ẹ wá, ẹ jẹ́ kí adarapọ̀ mọ́ Olúwa ní májẹ̀mú ayé-rayé,tí a kì yóò gbàgbé.

6. “Àwọn ènìyàn mi ti jẹ́ àgùntàn tí ó sọnù,àwọn olùṣọ́ àgùntàn wọn ti jẹ́ kí wọn sìnà,wọ́n ti jẹ́ kí wọn rìn lórí òkèwọ́n ti lọ láti orí òkè ńlá dé òkè kékeré,wọn ti gbàgbé ibùsùn wọn.

7. Gbogbo àwọn tí ó rí wọn, ti pa wọ́n jẹàwọn ọ̀ta wọ́n sì wí pé, ‘Àwa kò jẹ̀binítorí pé wọ́n ti sẹ̀ sí Olúwa ibùgbéòdodo àti ìrètí àwọn baba wọn.’

8. “Jáde kúrò ní Bábílónìfi ilẹ̀ àwọn ará Bábílónì sílẹ̀kí ẹ sì dàbí àgùntàn inú agbo tí à ń kó jẹ̀.

9. Nítorí pé èmi yóò ru,bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò gbé sókè sí Bábílónì àwọn orílẹ̀ èdèńlá láti ilẹ̀ àríwá. Wọn yóò gba àyà wọn lẹ́gbẹ́ rẹ̀;Láti àríwá wá, à ó sì mú ọ. Ọfà wọn yóòdàbí ọfà àwọn akọni alákíkanjú tí wọn kì í wà lọ́wọ́ òfo

10. A ó dààmú Bábílónì, gbogboàwọn tó dààmú rẹ yóò sì múìfẹ́ wọn sẹ,”ni Olúwa wí.

11. “Nítorí pé inú yín dùn nítorí pé ẹ̀yìn yọ̀,ẹ̀yìn olè tí ó jí ìní mi, nítorí tí ẹ̀yìnfi ayọ̀ fò bí ẹgbọ̀rọ̀ màlúù sí koríko tútù,ẹsì ń yan bí akọ-ẹsin.

12. Ojú yóò ti ìyá rẹ, ẹni tí ó bí ọyóò sì gba ìtìjú.Òun ni yóò jẹ́ kékeré jù nínú àwọn orílẹ̀ èdè,ilẹ̀ aṣálẹ̀ àti ihà tí kò lọ́ràá.

13. Nítorí ìbínú Olúwa, kì yóò ní olùgbé;ẹnikẹ́ni kò sì ní gbé inú rẹ̀.Gbogbo àwọn tí ó bá kọjá ni Bábílónì yóòfi ṣe yẹ̀yẹ́ nítorí ọgbẹ́ rẹ̀.

Jeremáyà 50