Jeremáyà 5:18-23 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

18. “Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì,” ni Olúwa wí, “Èmi kì yóò pa yín run pátapáta.

19. Àti pé, nígbà tí àwọn ènìyàn bá sì béèrè wí pé, ‘Kí ni ìdí rẹ̀ tí Olúwa Ọlọ́run wa fi ṣe gbogbo èyí sí wa?’ Ìwọ yóò sì sọ fún wọn wí pé, ‘Ẹ̀yin ti kọ̀mí sílẹ̀, ẹ sì ń sin Ọlọ́run àjèjì ní ilẹ̀ yín. Nísinsìnyìí, ẹ̀yin yóò máa sin àjèjì ní ilẹ̀ tí kì í ṣe ti yín.’

20. “Kéde èyí fún ilé Jákọ́bù,kí ẹ sì polongo rẹ̀ ní Júdà.

21. Gbọ́ èyí, ẹ̀yin aláìlóye àti aláìlọ́gbọ́n ènìyàn,tí ó lójú ti kò fi rírantí ó létí ti kò fi gbọ́ran.

22. Kò ha yẹ kí ẹ bẹ̀rù mi?” ni Olúwa wí.“Kò ha yẹ kí èyin ó wárìrì níwájú mi bí?Mo fi yanrìn pààlà òkun,èyí tí kò le è rékọjá rẹ̀ láéláé.Ìjì lè jà, kò le è borí rẹ̀;wọ́n le è bú, wọn kò le è rékọjá rẹ̀.

23. Ṣùgbọ́n, àwọn ènìyàn wọ̀nyí ní ọkàn líle àti ọkàn ọ̀tẹ̀,wọ́n ti yípadà, wọ́n sì ti lọ.

Jeremáyà 5