6. Wọ́n tún kó àwọn ọkùnrin, àwọn obìnrin àti àwọn ọmọdé, àti àwọn ọmọ Ọba tí ó jẹ́ obìnrin èyí tí Nebusàrádánì tí ó jẹ́ adarí ogun ọ̀wọ́ tí ó jẹ́ olùsọ́ ti fi sílẹ̀ pẹ̀lú Jedaháyà ọmọ Élíkámù, ọmọ Sáfánì, àti Jeremáyà wòlíì náà àti Bárúkù ọmọ Néríà.
7. Nítorí náà, wọn wọ Éjíbítì pẹ̀lú àìgbọ́ràn sí àṣẹ Olúwa, wọ́n sì lọ títí dé Táfánésì.
8. Ní Táfánésì ọ̀rọ̀ Olúwa tọ Jeremáyà wá:
9. “Nígbà tí àwọn Júù ń wòye mú àwọn òkúta pẹ̀lú rẹ, kí o sì rì wọ́n mọ́ inú amọ̀ tí ó wà nínú bíríkì tí ó wà níbi pèpéle ẹnu ọ̀nà ààfin Fáráò ní Táfánésì.
10. Báyìí kí o sì sọ fún wọn pé, ‘Èyí ni ohun tí Ọlọ́run alágbára, Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí: Èmi yóò ránsẹ́ sí ìránṣẹ́ mi Nebukadinésárì Ọba Bábílónì Èmi yóò gbé ìjọba rẹ̀ ka orí àwọn òkúta; èyí tí mo ti rì sí ibí yìí, yóò tan ìjọba rẹ̀ jù wọ́n lọ.