Jeremáyà 42:18-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

18. Báyìí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ ogun Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí: ‘Gẹ́gẹ́ bí èmi ti da ìbínú àti ìrunú síta sórí àwọn tí ó ń gbé ní Jérúsálẹ́mù, bẹ́ẹ̀ ni ìrunú mi yóò dà sita sórí yín, nígbà tí ẹ̀yin bá lọ sí Éjíbítì. Ẹ̀yin ó sì di ẹni ègún àti ẹní ẹ̀gàn àti ẹ̀sín, ẹ̀yin kì yóò sì rí ibí yìí mọ́.’

19. “Ẹ̀yin yóòkù Júdà, Olúwa ti sọ fún un yín pé, ‘Kí ẹ má ṣe lọ sí Éjíbítì.’ Ẹ mọ èyí dájú: Èmi kìlọ̀ fún un yín lónìí;

20. Pé àṣìṣe ńlá gbáà ni ẹ̀yin ṣe nígbà tí ẹ̀yin rán mi sí Olúwa Ọlọ́run yín pé, ‘Gbàdúrà sí Olúwa Ọlọ́run wa fún wa; sọ fún wa gbogbo ohun tí ó bá sọ, àwa yóò sì ṣe é.’

21. Mo ti sọ fún un yín lónìí, ṣùgbọ́n síbẹ̀ ẹ̀yin kò tí ì gbọ́ ohùn Olúwa Ọlọ́run yín, àti gbogbo ohun tí ó rán mi láti sọ fún un yín.

22. Ǹjẹ́ nísinsìnyìí ẹ mọ èyí dájú pé: Ẹ̀yin yóò kú nípa idà, ìyàn àti àjàkálẹ̀-àrùn níbikíbi tí ẹ̀yin bá fẹ́ lọ láti ṣe àtìpó.”

Jeremáyà 42