12. Wọ́n kó gbogbo àwọn ọkùnrin wọn, wọ́n sì, lọ bá Ísímáẹ́lì ọmọ Nétanáyà jà. Wọ́n pàdé rẹ̀ ní odò kan lẹ́bàá Gídéónì.
13. Nígbà tí gbogbo àwọn ènìyàn Ísímáẹ́lì tí wọ́n wà pẹ̀lú rẹ̀ rí Jóhánánì ọmọkùnrin Káréà àti àwọn ọmọ-ogun rẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀, wọ́n sì yọ̀.
14. Gbogbo àwọn ènìyàn tí Ísímáẹ́lì ti kó ní ìgbékùn ní Mísípà yípadà, wọ́n sì lọ sọ́dọ̀ Jóhánánì ọmọ Káréà.
15. Ṣùgbọ́n Ísímáẹ́lì ọmọkùnrin Nétanáyà àti àwọn mẹ́jọ nínú àwọn ọkùnrin rẹ̀ bọ́ lọ́wọ́ Jóhánánì, wọ́n sì sálọ sí Ámónì.
16. Lẹ́yìn náà Jóhánánì ọmọkùnrin Káréà àti gbogbo àwọn ọmọ ogun tí wọn wà pẹ̀lú rẹ̀ sì kó gbogbo àwọn tí ó kù ní Mísípà; àwọn tí ó ti rí gbà lọ́wọ́ Ísímáẹ́lì ọmọkùnrin Nétanáyà; lẹ́yìn ìgbà tí ó ti pa Gédáláyà ọmọ Álíkámù. Àwọn ọmọ ogun, àwọn obìnrin, àwọn ọmọdé àti àwọn olórí ilé ẹjọ́ tí ó ti kó wa láti Gíbíónì.