1. Ní oṣù keje Íṣímáẹ́lì ọmọkùnrin Netanáyà, ọmọkùnrin Élísámà ti ìdílé Ọba, tí ó sì ti jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìjòyè Ọba, tọ Jedaláyà ọmọ Áhíkámù ti Mísípà wá pẹ̀lú ọkùnrin mẹ́wàá. Nígbà tí wọ́n ń jẹun papọ̀.
2. Íṣímáẹ́lì ọmọ Netanáyà àti àwọn ọkùnrin mẹ́wàá tí wọ́n wà pẹ̀lú rẹ̀, sì dìde wọ́n kọlu Jedaláyà ọmọ Áhíkámù, ọmọ Sáfánì pẹ̀lú idà. Wọ́n sì pa á, ẹni tí Ọba Bábílónì ti yàn gẹ́gẹ́ bí gómìnà lórí ilẹ̀ náà.