Jeremáyà 4:17-28 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

17. Wọ́n yí i ká bí ìgbà tí àwọn ọkùnrin bá ń ṣọ́ pápá,nítorí pé ó ti dìtẹ̀ sí mi,’ ”ni Olúwa wí.

18. “Ìwà rẹ àti ìṣe rẹló fa èyí bá ọÌjìyà rẹ sì nìyìí,Báwo ló ti ṣe korò tó!Báwo ló ti ṣe gún ọkàn rẹ sí!”

19. Áà! Ìrora mi, ìrora mi!Mo yí nínú ìrora.Áà!, ìrora ọkàn mi!Ọkàn mi lù kìkì nínú mi,N kò le è dákẹ́.Nítorí mo ti gbọ́ ohùn ìpè,Mo sì ti gbọ́ igbe ogun.

20. Ìparun ń gorí ìparun;Gbogbo ilẹ̀ náà sì ṣubú sínú ìparunLọ́gán a wó àwọn àgọ́ mi,tí ó jẹ́ ohun ààbò mi níṣẹ́jú kan.

21. Yóò ti pẹ́ tó, tí èmi yóò rí oguntí èmi yóò sì gbọ́ ìró fèrè?

22. “Aṣiwèrè ni àwọn ènìyàn mi;wọn kò mọ̀ mí.Wọ́n jẹ́ aláìgbọ́n ọmọ;wọ́n sì jẹ́ aláìlóye.Wọ́n mọ ibi ṣíṣe;wọn kò mọ bí a ti í ṣe rere.”

23. Mo bojú wo ayé,ó sì wà ní júujùu, ó sì ṣófoàti ní ọ̀run,ìmọ́lẹ̀ wọn kò sì sí.

24. Mo wo àwọn òkè ńlá,wọ́n wárìrì;gbogbo òkè kékèké mì jẹ̀jẹ̀.

25. Mo wò yíká n kò rí ẹnìkan;gbogbo ẹyẹ ojú ọ̀run ló ti fò lọ.

26. Mo bojú wò, ilẹ̀ eléṣo, ó sì di aṣálẹ̀gbogbo àwọn ìlú inú rẹ̀ sì ṣubú sínú ìparunníwájú Olúwa àti níwájú ríru ìbínú rẹ̀.

27. Èyí ni ohun tí Olúwa wí“Gbogbo ìlú náà yóò sì di ahoro,síbẹ̀ èmi kì yóò pa á run pátapáta.

28. Nítorí náà, ayé yóò pohùnréré ẹkúnàwọn ọ̀run lókè yóò ṣóòkùnnítorí mo ti sọ, mo sì ti pète rẹ̀mo ti pinnu, n kì yóò sì yí i padà.”

Jeremáyà 4