15. Nígbà tí Jeremáyà wà nínú túbú, ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ ọ́ wá wí pé:
16. “Lọ sọ fún Ebedimélékì ará Kúṣì, ‘Èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun, Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí: Èmi ṣetan láti mú ọ̀rọ̀ mi ṣẹ lórí ìlú yìí nípa àjálù kì í ṣe àlàáfíà. Ní àkókò náà ni yóò ṣẹ lójú rẹ.
17. Ṣùgbọ́n Èmi yóò gbà ọ́ lọ́jọ́ náà ni Olúwa wí. A kò ní fi ọ́ lé ọwọ́ àwọn tí o bẹ̀rù.
18. Èmi yóò gbà ọ́ là; o kò ní ṣubú láti ipa idà; ṣùgbọ́n ìwọ yóò sá àsálà fún ẹ̀mí rẹ, nítorí pé ìwọ ní ìgbàgbọ́ nínú mi, ni Olúwa wí.’ ”