Jeremáyà 37:16-19 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

16. Wọ́n fi Jeremáyà sínú túbú tí ó ṣókùnkùn biribiri; níbi tí ó wà fún ìgbà pípẹ́.

17. Nígbà náà ni Ọba Sedekáyà ránṣẹ́ sí i, tí ó sì pàṣẹ pé kí wọ́n mú wá sí ààfin níbi tí ó ti bi í ní ìkọ̀kọ̀ pé, “Ìfẹ́ ọ̀rọ̀ kan wà láti ọ̀dọ̀ Olúwa?”“Bẹ́ẹ̀ ni,” Jeremáyà fèsì pé, “wọn ó fi ọ́ lé ọwọ́ Ọba Bábílónì.”

18. Nígbà náà, Jeremáyà sọ fún Ọba Sedekáyà pé, “Irú ẹ̀ṣẹ̀ wo ni mo ṣẹ̀ yín, àwọn ìjòyè yín pẹ̀lú àwọn ènìyàn tí ẹ fi sọ mí sínú túbú?

19. Níbo ni àwọn wòlíì yín tí wọ́n ń sọ àṣọtẹ́lẹ̀ fún-un yín wí pé Ọba Bábílónì kò ní gbógun tì yín wá?

Jeremáyà 37