21. O kó àwọn Ísírẹ́lì ènìyàn rẹ jáde láti Éjíbítì pẹ̀lú àmì àti ìyanu nínú ọwọ́ agbára àti nína apá rẹ pẹ̀lú ẹ̀rù ńlá.
22. Ìwọ fún wọn nílẹ̀ yìí, èyí tí o ti ṣèlérí fún àwọn baba ńlá wọn; ilẹ̀ tí ń ṣàn fún wàrà àti oyin.
23. Wọ́n wá, wọ́n sì gba ilẹ̀ náà ṣùgbọ́n wọn kò gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ tàbí tẹ̀lé òfin rẹ. Wọn kò ṣe ohun tí o paláṣẹ fún wọn, nítorí náà ìwọ mú àwọn ibi yìí wá sórí wọn.
24. “Wò ó, bí àwọn ìdọ̀tí ṣe korájọ láti gba ìlú. Nítorí idà, ìyàn àti àjàkálẹ̀-àrùn, sì fi ìlú lé ọwọ́ àwọn ará Kálídéà tí ń gbógun tì wọ́n. Ohun tí ìwọ sọ ṣẹ gẹ́gẹ́ bí o ṣe rí i.
25. Ṣíbẹ̀ à ò fi ìlú náà fún àwọn ará Kálídéà. Ìwọ Olúwa Ọba sọ fún mi pé, ‘Ra pápá náà pẹ̀lú owó fàdákà, kí o sì pe ẹlẹ́rìí.’ ”