1. Èyí ni ọ̀rọ̀ tó tọ Jeremáyà wá láti ọ̀dọ̀ Olúwa ní ọdún kẹwàá sédékáyà Ọba Júdà, èyí tí ó jẹ́ ọdún kejìdínlógún ti Nebukadinésárì.
2. Àwọn ogun Ọba Bábílónì ìgbà náà há Jérúsálẹ́mù mọ́. A sì ṣé wòlíì Jeremáyà mọ́ inú túbú tí wọ́n ń sọ́ ní àgbàlá ilé Ọba Júdà.
3. Nítorí Sedekáyà Ọba Júdà ti há a mọ́lé síbẹ̀; pé, “Kí ló dé tí ìwọ fi ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ báyẹn? Tí o sì wí pé, ‘Báyìí ni Olúwa wí: Èmi ń bọ̀ wá fi ìlú yìí fún Ọba Bábílónì, tí yóò sì gbà á.