39. Okùn ìwọ̀n yóò sì nà jáde láti ibi gígùn lọ sí òkè Gárébì yóò sì lọ sí Góà.
40. Gbogbo àfonífojì níbi tí wọ́n ń da òkú àti eérú sí, àti gbogbo àfonífojì odò Kídírónì ní ìhà ìlà oòrùn títí dé igun ẹnubodè ẹṣin yóò jẹ́ mímọ́ sí Olúwa. A kì yóò fa ìlú náà tu tàbí kí a wó o palẹ̀.”