Jeremáyà 3:11-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

11. Olúwa wí fún mi pé, “Ísírẹ́lì aláìnígbàgbọ́ ṣe òdodo ju Júdà tí ó ní Ìgbàgbọ́ lọ.

12. Lọ polongo ọ̀rọ̀ náà, lọ sí ìhà àríwá:“ ‘Yípadà, Ísírẹ́lì aláìnígbàgbọ́,’ ni Olúwa wí.‘Ojú mi kì yóò le sí yín mọ́,nítorí mo jẹ́ aláàánú, ni Olúwa wí.

13. Sá à ti mọ ẹ̀bi rẹ,o ti ṣọ̀tẹ̀ sí Olúwa Ọlọ́run rẹ,o ti wá ojú rere rẹ lọ́dọ̀ ọlọ́run àjèjìlábẹ́ gbogbo igikígi,tí ó tẹ́wọ́, o kò sì gbọ́ràn sí mi lẹ́nu,’ ”ni Olúwa wí.

14. “Padà, ẹ̀yin ènìyàn aláìnígbàgbọ́,” ni Olúwa wí, “nítorí èmi ni ọkọ rẹ. Èmi ó yàn ọ́, ọ̀kan láti ìlú àti méjì láti ẹ̀yà. Èmi ó sì mú ọ wá sí Síónì.

15. Lẹ́yìn èyí, èmi ó fún ọ ní àwọn olùṣọ́ àgùntàn láti inú ọkàn mi, tí wọn yóò ṣáájú yín pẹ̀lú òye àti ìmọ̀.

16. Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì, tí ẹ̀yin bá pọ̀ sí i lórí ilẹ̀ náà,” ni Olúwa wí, “àwọn ènìyàn kò tún lè sọ pé, ‘Àpótí ẹ̀rí Olúwa’ kò ní wá sí ìrántí wọn mọ́, a kì yóò pàdánù rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni a kì yóò sì tún kan òmíràn mọ́.

Jeremáyà 3