Jeremáyà 29:24-31 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

24. Wí fún Ṣemáyà tí í ṣe Neelamíyà pé,

25. “Èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run alágbára Ísírẹ́lì wí: Ìwọ fi lẹ́tà ránṣẹ́ sí gbogbo àwọn ènìyàn ní Jérúsálẹ́mù sí Sefanáyà ọmọ Mááséà tí í ṣe àlùfáà ní orúkọ mi; ó sì sọ fún Sefanáyà wí pé,

26. ‘Olúwa ti yàn ọ́ gẹ́gẹ́ bí àlùfáà rọ́pò Jéhóíádà láti máa jẹ́ alákóso ilé Olúwa, kí o máa fi èyíkéyìí nínú àwọn aṣiwèrè tó bá ṣe bí i wòlíì si inú àgò irin.

27. Nítorí náà, èéṣe tí o kò fi bá Jeremáyà ará Ánátótì wí. Ẹni tí ó ń dúró bí i wòlíì láàrin yín?

28. Ó ti rán iṣẹ́ yìí sí wa ni Bábílónì wí pé, àtìpó náà yóò pẹ́ kí ó tó parí, nítorí náà, ẹ kọ́ ilé kí ẹ sì máa gbé ibẹ̀, ẹ dá oko, kí ẹ sì máa jẹ èṣo ohun ọ̀gbìn oko yín.’ ”

29. Sefanáyà àlùfáà ka lẹ́tà náà sí etí ìgbọ́ Jérúsálẹ́mù tí í ṣe wòlíì.

30. Nígbà náà ni ọ̀rọ̀ Olúwa tọ Jeremáyà wá wí pé,

31. “Rán iṣẹ́ yìí sí gbogbo àwọn àtìpó: ‘Èyí ni ohun tí Olúwa sọ nípa Ṣemáyà àti Neelamaiti: Nítorí pé Semaíà ti sọ tẹ́lẹ̀ fún un yín, súgbọ́n èmi kò ran an, tí òun sì ń mú u yín gbẹ́kẹ̀lé èké.

Jeremáyà 29