Jeremáyà 29:11-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

11. Nítorí mo mọ ète tí mo ní fún un yín,” ni Olúwa wí, “Ète láti mú yín lọ́rọ̀ láìpa yín lára, ète láti fún un yín ní ìrètí ọjọ́ iwájú.

12. Nígbà náà ni ẹ̀yin yóò ké pè mí, tí ẹ̀yin yóò sì gbàdúrà sí mi, tí èmi yóò sì gbọ́ àdúrà yín.

13. Ẹ̀yin yóò wá mi, bí ẹ̀yin bá sì fi gbogbo ọkàn yín wá mi: ẹ̀yin yóò rí mi ni Olúwa Ọlọ́run wí.

14. Èmi yóò sì mú yín kúrò ní ìgbékùn. Èmi yóò ṣà yín jọ láti gbogbo orílẹ̀ èdè àti ibi gbogbo tí mo ti lé yín jáde. Èmi yóò sì kó yín padà sí Jérúsálẹ́mù ibi tí mo ti kó jáde lọ sí ilé àtìpó.”

15. Ẹ lè sọ pé, “Olúwa ti gbé àwọn wòlíì dìde fún wa ní Bábílónì.”

16. Ṣùgbọ́n èyí ni ọ̀rọ̀ Olúwa nípa Ọba tó jókòó lórí ìtẹ́ Dáfídì àti gbogbo àwọn ènìyàn tó ṣẹ́kù ní ìlú náà; àní àwọn ènìyàn ìlú yín tí kò lọ sí ilé àtìpó pẹ̀lú yín.

Jeremáyà 29