6. Ojú mi yóò máa ṣọ́ wọn lọ fún rere; Èmi yóò gbé wọn ró, n kò ní já wọn lulẹ̀. Èmi yóò gbìn wọ́n, n kò sì ní fà wọ́n tu.
7. Èmi yóò fún wọn ní ọkàn láti mọ̀ mí pé, Èmi ni Olúwa. Wọn yóò jẹ́ ènìyàn mi; Èmi ni yóò sì jẹ́ Ọlọ́run wọn; nítorí pé wọn yóò padà sọ́dọ̀ mi pẹ̀lú gbogbo ọkàn wọn.
8. “ ‘Ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí èṣo ọ̀pọ̀tọ́ tí kò dára, tí ó burú tí kò ṣe é jẹ,’ ni Olúwa wí, ‘bẹ́ẹ̀ ni Èmi yóò ṣe pẹ̀lú Ṣedekáyà Ọba Júdà, àwọn ìjòyè rẹ̀ àti àwọn tí ó yẹ ní Jérúsálẹ́mù, yálà wọ́n wà lórí ilẹ̀ yìí tàbí wọ́n ń gbé Éjíbítì.