Jeremáyà 23:33-37 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

33. “Nígbà tí àwọn ènìyàn wọ̀nyí, tàbí wòlíì tàbí àlùfáà bá bi ọ́ léèrè wí pé, ‘Kí ni ọ̀rọ̀ ìjìnlẹ̀ Olúwa?’ Sọ fún wọn wí pé, ‘ọ̀rọ̀ ìjìnlẹ̀ wo? Èmi yóò pa yín tì ni Olúwa wí.’

34. Bí wòlíì tàbí àlùfáà tàbí ẹnikẹ́ni bá sì gbà wí pé, ‘Èyí ni ọ̀rọ̀ ìjìnlẹ̀ Olúwa.’ Èmi yóò fi ìyà jẹ ọkùnrin náà àti gbogbo agbo ilé rẹ̀.

35. Èyí ni ohun tí ẹnìkọ̀ọ̀kan yín ń sọ fún ọ̀rẹ́ àti ará ilé rẹ̀: ‘Kí ni ìdáhùn Olúwa?’ tàbí ‘Kíni ohun tí Olúwa sọ?’

36. Ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò gbọdọ̀ dárúkọ ọ̀rọ̀ ‘ìjìnlẹ̀ Olúwa’ mọ́, nítorí pé ọ̀rọ̀ oníkálùkù ènìyàn di ọ̀rọ̀ ìjìnlẹ̀ rẹ̀. Nítorí náà, ẹ̀yin ń yí ọ̀rọ̀ Olúwa Ọlọ́run alágbára alààyè padà.

37. Èyí ni ohun tí ẹ̀yin ń sọ fún wòlíì: ‘Kí ni ìdáhùn Olúwa sí ọ́?’ tàbí ‘Kí ni ohun tí Olúwa bá ọ sọ?’

Jeremáyà 23