20. Ìbínú Olúwa kì yóò yẹ̀títí tí yóò sì fi mú èrò rẹ̀ ṣẹ,ní àìpẹ́ ọjọ́, yóò yé e yín yékéyéké.
21. Èmi kò rán àwọn wòlíì wọ̀nyísíbẹ̀ wọ́n lọ pẹ̀lú ọ̀rọ̀ wọn.Èmi kò tilẹ̀ bá wọn sọ̀rọ̀,síbẹ̀ wọ́n sọ àṣọtẹ́lẹ̀,
22. Ṣùgbọ́n ìbáṣepọ̀ wọn dúró nínú ìgbìmọ̀ mi,wọn ì bá ti kéde ọ̀rọ̀ mi fún àwọn ènìyàn mi.Wọn ì bá ti wàásù ọ̀rọ̀ mi sí àwọn ènìyànwọn ìbá ti yípadà kúrò nínú ọ̀nààti ìṣe búburú wọn.
23. “Ǹjẹ́ Ọlọ́run tòsí nìkan ni Èmi bí?”ni Olúwa wí,“kì í sì í ṣe Ọlọ́run ọ̀nà jínjìn.
24. Ǹjẹ́ ẹnikẹ́ni lè sá pamọ́ sí ibi kọ́lọ́fín kan,kí èmi má ba a rí?”ni Olúwa wí.“Ǹjẹ́ èmi kò há a kún ọ̀run àti ayé bí?”ni Olúwa wí.
25. “Mo ti gbọ gbogbo ohun tí àwọn wòlíì èké tí ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ ní orúkọ mi ń sọ. Wọ́n sọ wí pé, ‘Mo lá àlá! Mo lá àlá!’
26. Títí di ìgbà wo ni èyí yóò fi máa tẹ̀ṣíwájú ni ọkàn àwọn wòlíì èké wọ̀nyí tí wọ́n ń sọ ìtànjẹ ọkàn wọn?
27. Wọ́n rò wí pé àlá tí wọ́n ń sọ fún ara wọn yóò mú kí àwọn ènìyàn mi gbàgbé orúkọ mi, gẹ́gẹ́ bí àwọn baba wọn ṣe gbàgbé orúkọ mi nípa sísin òrìṣà Báálì.