Jeremáyà 23:15-19 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

15. Nítorí náà, báyìí ni OlúwaỌlọ́run alágbára wí ní ti àwọn wòlíì:“Èmi yóò mú wọn jẹ oúnjẹ kíkorò,wọn yóò mu omi májèlénítorí láti ọ̀dọ̀ àwọn wòlíì Jérúsálẹ́mùni àìwà-bí-Ọlọ́run ti tàn ká gbogbo ilẹ̀.”

16. Èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí,“Ẹmá ṣe fi etí sí àṣọtẹ́lẹ̀ tí àwọn wòlíì èké ń sọ fún un yín.Wọ́n ń kún inú ọkàn yín pẹ̀lú ìrètí asán.Wọ́n ń sọ ìran láti ọkàn ara wọn,kì í ṣe láti ẹnu Olúwa.

17. Wọ́n ń sọ fún àwọn tí ó ń gàn mí pé,‘Olúwa ti wí pé: Ẹ ó ní àlàáfíà,’Wọ́n sì wí fún gbogbo àwọn tí ó rìn nípa agídí ọkàn rẹ̀ pé,‘Kò sí ìpalára kan tí yóò ṣẹlẹ̀ sí yín.’

18. Ṣùgbọ́n èwo nínú wọn ni ó dúrónínú ìgbìmọ̀ Olúwa láti rí itàbí gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀?Ta ni ó gbọ́ tí ó sì fetí sí ọ̀rọ̀ náà?

19. Wò ó, afẹ́fẹ́ Olúwa yóò tú jádepẹ̀lú ìbínú àfẹ́yíká ìjì yóò fẹ́ síorí àwọn olùṣe búburú.

Jeremáyà 23