Jeremáyà 22:28-30 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

28. Ǹjẹ́ Jéhóíákínì ẹni ẹ̀gàn yàtọ̀ sí ìkòkò òfìfo,ohun èlò tí ẹnìkan kò fẹ́?Èéṣe tí a fi òun àti àwọn ọmọ rẹ̀ sókèsí ilẹ̀ tí wọn kò mọ̀.

29. Ìwọ ilẹ̀, ilẹ̀, ilẹ̀,gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa!

30. Báyìí ni Olúwa wí:“Kọ àkọsílẹ̀ ọkùnrin yìí sínú ìwé gẹ́gẹ́ bí aláìlọ́mọ,ẹni tí kì yóò ṣe rere ní ọjọ́ ayé rẹ̀;nítorí ọ̀kan nínú irú ọmọ rẹ̀ kì yóò ṣe rere,èyíkéyìí wọn kì yóò jókòó lórí ìtẹ́ Dáfídìtàbí jọba ní Júdà mọ́.”

Jeremáyà 22