10. Nítorí náà má ṣe sunkún nítorí Ọba tí ó ti kú tàbí sọ̀fọ̀ fún àdánù rẹ̀,ṣùgbọ́n ẹ sunkún kíkorò fún ẹni tí a lé kúrò nílùúnítorí kì yóò padà wá mọ́tàbí fi ojú rí ilẹ̀ tí a ti bí i.
11. Nítorí báyìí ni Olúwa wí, nípa Ṣálúmù ọmọ Jòsáyà Ọba Júdà tí ó jọba lẹ́yìn baba rẹ̀, ṣùgbọ́n tí ó jáde kúrò níhìn ín: “Òun kì yóò padà wá mọ́.
12. Yóò kú ni ibi tí a mú u ní ìgbèkùn lọ, kì yóò sì rí ilẹ̀ yìí mọ́.”
13. “Ègbé ni fún ẹni tí a kọ́ ààfin rẹ̀ lọ́nà àìsòdodo,àti àwọn yàrá òkè rẹ̀ lọ́nà àìtọ́tí ó mú kí àwọn ará ìlú rẹ ṣiṣẹ́ lásánláì san owó iṣẹ́ wọn fún wọn.
14. Ó wí pé, ‘Èmi ó kọ́ ààfin ńlá fún ara miàwọn yàrá òkè tí ó fẹ̀,ojú fèrèsé rẹ̀ yóò tóbi.’A ó sì fi igi kédárì bò ó,a ó fi ohun aláwọ̀ pupa ṣe é ní ọ̀ṣọ́.
15. “Nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ igi kédárì, a sọ ọ́ di Ọbababa rẹ kò ha ní ohun jíjẹ àti mímu?Ó ṣe ohun tí ó tọ́ ni ó fi dára fún un.
16. Ó gbéjà òtòsì àti aláìní,ohun gbogbo sì dára fún un.Ìyẹn ha kọ́ ni mímọ́ mi túmọ̀ sí?”ni Olúwa wí.
17. “Ṣùgbọ́n ojú àti ọkàn rẹwà lára rẹ̀ ní èrè àìsòtítọ́láti ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀ìnilára àti ìlọ́nilọ́wọ́gbà.”
18. Nítorí náà báyìí ni Olúwa wí, nípa Jehóíákímù ọmọ Jòsáyà, Ọba Júdà:“Wọn kì yóò ṣọ̀fọ̀ fún un:wí pé, ‘Ó ṣe, arákùnrin mi! Ó ṣe, arábìnrin mi!’Wọn kì yóò sọ̀fọ̀ fún un:wí pé, ‘Ó ṣe, olúwa tàbí ó ṣe kábíyèsí!’
19. A ó sin òkú rẹ̀ bí i kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́tí a wọ́ sọnù gba ti ẹnubodèJérúsálẹ́mù.”
20. “Gòkè lọ sí Lẹ́bánónì, kígbe sítakí a sì gbọ́ ohùn rẹ ní Básánì,kí o kígbe sókè láti Ábárímù,nítorí a ti run gbogbo àwọn olùfẹ́ rẹ túútúú.
21. Èmi ti kìlọ̀ fún ọ nígbà tí o rò pé kò séwu,ṣùgbọ́n o sọ pé, ‘Èmi kì yóò fetísílẹ̀!’Èyí ni iṣẹ́ rẹ láti ìgbà èwe rẹ,ìwọ kò fìgbà kan gba ohùn mi gbọ́.
22. Ẹ̀fúùfù yóò lé gbogbo àwọn olùṣọ́-àgùntàn rẹ̀ lọ,gbogbo àwọn olùfẹ́ rẹ yóò lọ sí ìgbékùn,nígbà náà ni a ó kẹ́gàn rẹ, ojú yóò tì ọ́nítorí gbogbo ìwà búburú rẹ.
23. Ìwọ tí ń gbé ‘Lẹ́bánónì,’tí ó tẹ́ ìtẹ́ sí orí igi kédárì,ìwọ yóò ti kérora pẹ́ tó, nígbà tí ìrora bá dé bá ọ,ìrora bí i ti obìnrin tí ń rọbí!
24. “Dájúdájú bí èmi ti wà láàyè,” ni Olúwa wí, “Bí Jéhóíákínì ọmọ Jéhóíákímù Ọba Júdà tilẹ̀ jẹ́ òrùka èdìdì lọ́wọ́ ọ̀tún mi, síbẹ̀ èmi ó fà ọ́ tu kúrò níbẹ̀.
25. Èmi ó sì fà ọ́ lé ọwọ́ àwọn tí ó ń wá ẹ̀mí rẹ, àwọn tí ìwọ bẹ̀rù, àní lé ọwọ́ Nebukadinésárì, Ọba Bábílónì àti ọwọ́ àwọn ará Bábílónì.
26. Èmi ó fi ìwọ àti ìyá tí ó bí ọ sọ̀kò sí ilẹ̀ mìíràn, níbi tí a kò bí ẹnikẹ́ni nínú yín sí. Níbẹ̀ ni ẹ̀yin méjèèjì yóò kú sí.
27. Ẹ̀yin kì yóò padà sí ilẹ̀ tí ẹ̀yin fẹ́ mọ́ láéláé.”
28. Ǹjẹ́ Jéhóíákínì ẹni ẹ̀gàn yàtọ̀ sí ìkòkò òfìfo,ohun èlò tí ẹnìkan kò fẹ́?Èéṣe tí a fi òun àti àwọn ọmọ rẹ̀ sókèsí ilẹ̀ tí wọn kò mọ̀.