Jeremáyà 22:1-3 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Báyìí ni Olúwa wí, “Sọ̀kalẹ̀ lọ sí ààfin Ọba Júdà, kí o sì sọ ọ̀rọ̀ yìí níbẹ̀:

2. ‘Gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa ìwọ Ọba Júdà, tí ó jókòó ní Ìtẹ́ Dáfídì, ìwọ, àwọn ènìyàn rẹ àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ, tí ó wọlé láti ẹnu ibodè wọ̀nyí.

3. Báyìí ni Olúwa wí: Ṣé ohun tí ó jẹ́ òtítọ́ tí ó sì yẹ, kí o sì gba ẹni tí a fi ẹ̀tọ́ rẹ̀ dù ú kúrò lọ́wọ́ aninilára. Má ṣe hu ìwà ìpanilára, tàbí opó, ìwọ kò sì gbọdọ̀ ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀ níbí yìí.

Jeremáyà 22