Jeremáyà 18:8-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

8. Tí orílẹ̀ èdè ti mo kìlọ̀ fún bá yípadà kúrò nínú ìwà búburú wọn, nígbà náà ni Èmi yóò yí ọkàn mi padà níbi àjálù tí mo ti rò láti ṣe sí wọn.

9. Ní ìgbà mìíràn tí èmi bá tún kéde láti tẹ̀dó tàbí gbin orílẹ̀ èdè kan tàbí ìjọba kan.

10. Tí ó sì ṣe búburú ní ojú mi, tí kò sì gbọ́ ọ̀rọ̀ mi, nígbà náà ni èmi yóò tún ṣe rere tí mo ti fẹ́ ṣe fún wọn.

Jeremáyà 18