Jeremáyà 18:18-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

18. Wọ́n sọ wí pé, “Wá, jẹ́ kí a lọ ṣọ̀tẹ̀ sí Jeremáyà, nítorí òfin ikọ́ni láti ẹnu àwọn àlùfáà kì yóò já sí asán, tàbí ìmọ̀ràn fún àwọn ọlọ́gbọ́n tàbí ọ̀rọ̀ láti ẹnu àwọn wòlíì. Nítorí náà wá, ẹ jẹ́ kí a kọlùú pẹ̀lú ahọ́n wa, kí a má sì ṣe tẹ́tí sí ohun kóhun tí ó bá sọ.”

19. Dẹtí sí ọ̀rọ̀ mi Olúwa, gbọ́ ohuntí àwọn tí ó fi mí sùn ń sọ.

20. Ṣe kí a fi rere san búburú?Síbẹ̀ wọ́n ti gbẹ́ kòtò fún mi,rántí pé mo dúró níwájú rẹ,mo sì sọ̀rọ̀ ní torí wọn, látiyí ìbínú rẹ kúrò lọ́dọ̀ wọn.

Jeremáyà 18