12. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n gbààwẹ̀, èmi kò ní tẹ́tí sí igbe wọn. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n rúbọ ọrẹ sísun àti ẹbọ ọkà, èmi ò ní gbà wọ́n. Dípò bẹ́ẹ̀, èmi ó fi idà, ìyànu àti àjàkálẹ̀-àrùn pa wọ́n run.”
13. Ṣùgbọ́n mo sọ pé, “Áà! Olúwa tí ó pọ̀ ní ipá. Wòlíì ń sọ fún wọn pé, ‘ẹ kò rí idà tàbí ìyàn. Dájúdájú èmi ó fún yín ní àlàáfíà tí yóò tọ́jọ́ níbí yìí?’ ”
14. Nígbà náà Olúwa sọ fún mi pé, “Àwọn wòlíì ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ èké ní orúkọ mi. Èmi kò rán wọn, tàbí yàn wọ́n tàbí bá wọn sọ̀rọ̀. Ìran èké ni wọ́n ń rí sí i yín. Àsọtẹ́lẹ̀ èké ni wọ́n ń sọ fún un yín nípa ìran ìrírí, àfọ̀ṣẹ, ìbọ̀rìṣà àti ìtànjẹ ọkàn wọn.