18. Sọ fún Ọba àti ayaba pé,“Ẹ rẹ ara yín sílẹ̀,ẹ sọ̀kalẹ̀ láti orí ìtẹ́ yín,adé ògo yín bọ́ sí ilẹ̀ láti orí yín.”
19. Àwọn orílẹ̀ èdè tí ó wà ní Négéfì ni à ó tì pa,kò sì ní sí ẹnikẹ́ni láti sí wọn.Gbogbo Júdà ni a ó kó lọ sí ilẹ̀ ìgbèkùn,gbogbo wọn ni a ó kó lọ pátapáta.
20. Gbé ojú rẹ sókè,kí o sì wo àwọn tí ó ń bọ̀ láti àríwá.Níbo ni agbo ẹran tí a fi sí abẹ́ àkóso rẹ wà;àgùntàn tí ò ń mú yangàn.
21. Kí ni ìwọ yóò wí nígbà tí Olúwa bá dúró lórí rẹàwọn tí o mú bí ọ̀rẹ́ àtàtà.Ǹjẹ́ kò ní jẹ́ ìrora fún ọbí aboyún tó ń rọbí?