10. Wọ́n ti padà sí ìdí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn baba ńlá wọn tí ó kọ̀ láti tẹ́tí sí ọ̀rọ̀ mi, wọ́n ti tẹ̀lé àwọn Ọlọ́run mìíràn láti sìn wọ́n. Ilé Ísírẹ́lì àti ilé Júdà ti fọ́ májẹ̀mú tí mo ṣe pẹ̀lú àwọn baba ńlá wọn.
11. Nítorí náà, èyí ni ohun tí Olúwa wí: ‘Èmi yóò mu ibi tí wọn kò ní le è yẹ̀ wá sorí wọn, bí wọ́n tilẹ̀ ké pè mí èmi kì yóò fetí sí igbe wọn.
12. Àwọn ìlú Júdà àti àwọn ará Jérúsálẹ́mù yóò lọ kégbe sí àwọn òrìṣà tí wọ́n ń sun tùràrí sí; àwọn òrìṣà náà kò ní ràn wọ́n lọ́wọ́ ní ìgbà tí ìpọ́nju òhún bá dé.
13. Bí iye àwọn ìlú yín ṣe pọ̀ tó náà ni àwọn òrìṣà yín. Ìwọ Júdà: àwọn pẹpẹ tí o ti pèsè fún jíjó tùràrí sí àwọn Báálì, òrìṣà yẹ̀yẹ́ sì pọ̀ bí iye òpópó tí ó wà ní Jérúsálẹ́mù.’